Rut 2 YCE

Rutu Ṣiṣẹ́ ninu Oko Boasi

1 NAOMI si ní ibatan ọkọ rẹ̀ kan, ọlọrọ̀ pupọ̀, ni idile Elimeleki; orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Boasi.

2 Rutu ara Moabu si wi fun Naomi pe, Jẹ ki emi lọ si oko nisisiyi, ki emi si ma peṣẹ́-ọkà lẹhin ẹniti emi o ri õre-ọfẹ́ li oju rẹ̀. On si wipe, Lọ, ọmọbinrin mi.

3 On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki.

4 Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ.

5 Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi?

6 Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa.

7 O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile.

8 Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin.

9 Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn.

10 Nigbana ni o wolẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba silẹ, o si wi fun u pe, Eṣe ti mo ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹ̃ni alejo li emi?

11 Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí.

12 Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle.

13 Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin.

14 Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ.

15 Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi.

16 Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi.

17 Bẹ̃li o peṣẹ́-ọkà li oko titi o fi di aṣalẹ, o si gún eyiti o kójọ, o si to bi òṣuwọn efa ọkà-barle kan.

18 O si gbé e, o si lọ si ilu: iya-ọkọ rẹ̀ si ri ẽṣẹ́ ti o pa: on si mú jade ninu eyiti o kù lẹhin ti o yó, o si fi fun u.

19 Iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ gbé peṣẹ́ li oni? nibo ni iwọ si ṣiṣẹ? ibukún ni fun ẹniti o fiyesi ọ. O si sọ ọdọ ẹniti on ṣiṣẹ fun iya-ọkọ rẹ̀, o si wipe, Boasi li orukọ ọkunrin ti mo ṣiṣẹ lọdọ rẹ̀ li oni.

20 Naomi si wi fun aya-ọmọ rẹ̀ pe, Ibukún ni fun u lati ọdọ OLUWA wá, ẹniti kò dẹkun ore rẹ̀ lati ṣe fun awọn alãye, ati fun awọn okú. Naomi si wi fun u pe, ọkunrin na sunmọ wa, ibatan ti o sunmọ wa ni.

21 Rutu obinrin Moabu na si wipe, O wi fun mi pẹlu pe, Ki iwọ ki o faramọ́ awọn ọdọmọkunrin mi, titi nwọn o fi pari gbogbo ikore mi.

22 Naomi si wi fun Rutu aya-ọmọ rẹ̀ pe, O dara, ọmọbinrin mi, ki iwọ ki o ma bá awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe bá ọ pade li oko miran.

23 Bẹ̃li o faramọ́ awọn ọmọbinrin ọdọ Boasi lati ma peṣẹ́-ọkà titi ipari ikore ọkà-barle ati ti alikama; o si wà lọdọ iya-ọkọ rẹ̀.

orí

1 2 3 4