13 Nigbana li o wipe, OLUWA mi, jẹ ki emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ; iwọ sá tù mi ninu, iwọ sá si ti sọ̀rọ rere fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, bi o tilẹ ṣe pe emi kò ri bi ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ rẹ obinrin.
14 Li akokò onjẹ, Boasi si wi fun u pe, Iwọ sunmọ ihin, ki o si jẹ ninu onjẹ, ki o si fi òkele rẹ bọ̀ inu ọti kíkan. On si joko lẹba ọdọ awọn olukore: o si nawọ́ ọkà didin si i, o si jẹ, o si yó, o si kùsilẹ.
15 Nigbati o si dide lati peṣẹ́-ọkà, Boasi si paṣẹ fun awọn ọmọkunrin rẹ̀, wipe, Ẹ jẹ ki o peṣẹ́-ọkà ani ninu awọn ití, ẹ má si ṣe bá a wi.
16 Ki ẹ si yọ diẹ ninu ití fun u, ki ẹ si fi i silẹ, ki ẹ si jẹ ki o ṣà a, ẹ má si ṣe bá a wi.
17 Bẹ̃li o peṣẹ́-ọkà li oko titi o fi di aṣalẹ, o si gún eyiti o kójọ, o si to bi òṣuwọn efa ọkà-barle kan.
18 O si gbé e, o si lọ si ilu: iya-ọkọ rẹ̀ si ri ẽṣẹ́ ti o pa: on si mú jade ninu eyiti o kù lẹhin ti o yó, o si fi fun u.
19 Iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ gbé peṣẹ́ li oni? nibo ni iwọ si ṣiṣẹ? ibukún ni fun ẹniti o fiyesi ọ. O si sọ ọdọ ẹniti on ṣiṣẹ fun iya-ọkọ rẹ̀, o si wipe, Boasi li orukọ ọkunrin ti mo ṣiṣẹ lọdọ rẹ̀ li oni.