3 On si lọ, o si dé oko, o si peṣẹ́-ọkà lẹhin awọn olukore: o si wa jẹ pe apa oko ti o bọ si jẹ́ ti Boasi, ti iṣe ibatan Elimeleki.
4 Si kiyesi i, Boasi ti Betilehemu wá, o si wi fun awọn olukore pe, Ki OLUWA ki o wà pẹlu nyin. Nwọn si da a lohùn pe, Ki OLUWA ki o bukún fun ọ.
5 Nigbana ni Boasi wi fun iranṣẹ rẹ̀ ti a fi ṣe olori awọn olukore pe, Ọmọbinrin tani yi?
6 Iranṣẹ na ti a fi ṣe olori awọn olukore dahùn, o si wipe, Ọmọbinrin ara Moabu ni, ti o bá Naomi ti ilẹ Moabu wa.
7 O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ma peṣẹ-ọkà, ki emi si ma ṣà lẹhin awọn olukore ninu ití: bẹ̃li o wá, o si duro ani lati owurọ̀ titi di isisiyi, bikoṣe ìgba diẹ ti o simi ninu ile.
8 Nigbana ni Boasi wi fun Rutu pe, Iwọ kò gbọ́, ọmọbinrin mi? Máṣe lọ peṣẹ́-ọkà li oko miran, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe re ihin kọja, ṣugbọn ki o faramọ́ awọn ọmọbinrin mi nihin.
9 Jẹ ki oju rẹ ki o wà ninu oko ti nwọn nkore rẹ̀, ki iwọ ki o si ma tẹle wọn: emi kò ha ti kìlọ fun awọn ọmọkunrin ki nwọn ki o máṣe tọ́ ọ? ati nigbati ongbẹ ba ngbẹ ọ, lọ si ibi àmu, ki o si mu ninu eyiti awọn ọmọkunrin ti pọn.