12 Njẹ nisisiyi ibatan ti o sunmọ nyin li emi iṣe nitõtọ: ṣugbọn ibatan kan wà ti o sunmọ nyin jù mi lọ.
13 Duro li oru yi, yio si ṣe li owurọ̀, bi on o ba ṣe iṣe ibatan si ọ, gẹgẹ; jẹ ki o ṣe iṣe ibatan: ṣugbọn bi kò ba fẹ́ ṣe iṣe ibatan si ọ, nigbana ni emi o ṣe iṣe ibatan si ọ, bi OLUWA ti wà: dubulẹ titi di owurọ̀.
14 On si dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀ titi di owurọ̀: o si dide ki ẹnikan ki o to mọ̀ ẹnikeji. On si wipe, Má ṣe jẹ ki a mọ̀ pe obinrin kan wá si ilẹ-ipakà.
15 O si wipe, Mú aṣọ-ileke ti mbẹ lara rẹ wá, ki o si dì i mú: nigbati o si dì i mú, o wọ̀n òṣuwọn ọkà-barle mẹfa, o si gbé e rù u: on si wọ̀ ilu lọ.
16 Nigbati o si dé ọdọ iya-ọkọ rẹ̀, on wipe, Iwọ tani nì ọmọbinrin mi? O si wi gbogbo eyiti ọkunrin na ṣe fun on fun u.
17 O si wipe, Òṣuwọn ọkà-barle mẹfa wọnyi li o fi fun mi; nitori o wi fun mi pe, Máṣe ṣanwọ tọ̀ iya-ọkọ rẹ lọ.
18 Nigbana li on wipe, Joko jẹ, ọmọbinrin mi, titi iwọ o fi mọ̀ bi ọ̀ran na yio ti jasi: nitoripe ọkunrin na ki yio simi, titi yio fi pari ọ̀ran na li oni.