3 Nitorina wẹ̀, ki o si para, ki o si wọ̀ aṣọ rẹ, ki o si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà: ṣugbọn má ṣe jẹ ki ọkunrin na ki o ri ọ titi on o fi jẹ ti on o si mu tán.
4 Yio si ṣe, nigbati o ba dubulẹ, ki iwọ ki o kiyesi ibi ti on o sùn si, ki iwọ ki o wọle, ki o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ki o si dubulẹ; on o si sọ ohun ti iwọ o ṣe fun ọ.
5 O si wi fun u pe, Gbogbo eyiti iwọ wi fun mi li emi o ṣe.
6 O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u.
7 Nigbati Boasi si jẹ ti o si mu tán, ti inu rẹ̀ si dùn, o lọ dubulẹ ni ikangun ikójọ ọkà: on si wá jẹjẹ, o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dubulẹ.
8 O si ṣe lãrin ọganjọ ẹ̀ru bà ọkunrin na, o si yi ara pada: si kiyesi i, obinrin kan dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀.
9 O si wipe, Iwọ tani? On si dahùn wipe, Emi Rutu ọmọbinrin ọdọ rẹ ni: nitorina nà eti-aṣọ rẹ bò ọmọbinrin ọdọ rẹ; nitori iwọ ni ibatan ti o sunmọ wa.