20 Eyiti o ti ṣiṣẹ ninu Kristi, nigbati o ti jí dide kuro ninu okú, ti o si fi i joko li ọwọ́ ọtún ninu awọn ọrun,
21 Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu.
22 O si ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀, o si ti fi i ṣe ori lori ohun gbogbo fun ijọ,
23 Eyiti iṣe ara rẹ̀, ẹkún ẹniti o kún ohun gbogbo ninu ohun gbogbo.