1 NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n;
2 Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun.
3 Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́;
4 Ibã ṣe ìwa ọ̀bun, ati isọ̀rọ wère, tabi iṣẹ̀fẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã dupẹ.
5 Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.
6 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran.
7 Nitorina ẹ máṣe jẹ alajọpin pẹlu wọn.
8 Nitori ẹnyin ti jẹ òkunkun lẹ̃kan, ṣugbọn nisisiyi, ẹnyin di imọlẹ nipa ti Oluwa: ẹ mã rìn gẹgẹ bi awọn ọmọ imọlẹ:
9 (Nitori eso Ẹmí wà niti iṣore gbogbo, ati ododo, ati otitọ;)
10 Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa.
11 Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi.
12 Nitori itiju tilẹ ni lati mã sọ̀rọ nkan wọnni ti nwọn nṣe nikọ̀kọ.
13 Ṣugbọn ohun gbogbo ti a mba wi ni imọlẹ ifi han: nitori ohunkohun ti o ba fi nkan hàn, imọlẹ ni.
14 Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ.
15 Nitorina ẹ kiyesi lati mã rìn ni ìwa pipé, kì iṣe bi awọn alailọgbọn, ṣugbọn bi awọn ọlọgbọn;
16 Ẹ mã ra ìgba pada, nitori buburu li awọn ọjọ.
17 Nitorina ẹ máṣe jẹ alailoye, ṣugbọn ẹ mã moye ohun ti ifẹ Oluwa jasi.
18 Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí;
19 Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa;
20 Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa;
21 Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun.
22 Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi fun Oluwa.
23 Nitoripe ọkọ ni iṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi ti ṣe ori ijọ enia rẹ̀: on si ni Olugbala ara.
24 Nitorina gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ̃ si ni ki awọn aya ki o mã ṣe si ọkọ wọn li ohun gbogbo.
25 Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u;
26 Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi,
27 Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku.
28 Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀.
29 Nitori kò si ẹnikan ti o ti korira ara rẹ̀; bikoṣepe ki o mã bọ́ ọ ki o si mã ṣikẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi si ti nṣe si ìjọ.
30 Nitoripe awa li ẹ̀ya-ara rẹ̀, ati ti ẹran-ara rẹ̀, ati ti egungun ara rẹ̀.
31 Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, on o si dàpọ mọ́ aya rẹ̀, awọn mejeji a si di ara kan.
32 Aṣiri nla li eyi: ṣugbọn emi nsọ nipa ti Kristi ati ti ijọ.
33 Ṣugbọn ki olukuluku nyin ki o fẹran aya rẹ̀ bẹ̃ gẹgẹ bi on tikararẹ̀; ki aya ki o si bẹru ọkọ rẹ̀.