7 Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀;
8 Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye,
9 Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀,
10 Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀:
11 Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀:
12 Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi;
13 Ninu ẹniti, ẹnyin pẹlu, nigbati ẹnyin ti gbọ ọrọ otitọ nì, ihinrere igbala nyin, ninu ẹniti nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ́ ileri nì ṣe edidi nyin,