1 NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n;
2 Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun.
3 Ṣugbọn àgbere, ati gbogbo ìwa ẽrí, tabi ojukòkoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ larin nyin mọ́, bi o ti yẹ awọn enia mimọ́;
4 Ibã ṣe ìwa ọ̀bun, ati isọ̀rọ wère, tabi iṣẹ̀fẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã dupẹ.
5 Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.