1 PAULU ati Timotiu, awọn iranṣẹ Jesu Kristi, si gbogbo awọn enia mimọ́ ninu Kristi Jesu ti o wà ni Filippi, pẹlu awọn biṣopu ati awọn diakoni:
2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Oluwa Jesu Kristi.
3 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe,
4 Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ,
5 Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi.