Filp 4 YCE

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú

1 NITORINA, ẹnyin ará mi olufẹ, ti mo si nṣafẹri gidigidi, ayọ̀ ati ade mi, ẹ duro ṣinṣin bẹ̃ ninu Oluwa, ẹnyin olufẹ mi.

2 Emi mbẹ̀ Euodia, mo si mbẹ̀ Sintike, ki nwọn ni inu kanna ninu Oluwa.

3 Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.

4 Ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa nigbagbogbo: mo si tún wi, Ẹ mã yọ̀.

5 Ẹ jẹ ki ipamọra nyin di mimọ̀ fun gbogbo enia. Oluwa mbẹ nitosi.

6 Ẹ máṣe aniyàn ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ mã fi ìbere nyin hàn fun Ọlọrun.

7 Ati alafia Ọlọrun, ti o jù ìmọran gbogbo lọ, yio ṣọ ọkàn ati ero nyin ninu Kristi Jesu.

8 Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.

9 Nkan wọnni, ti ẹnyin ti kọ́, ti ẹnyin si ti gbà, ti ẹnyin si ti gbọ́, ti ẹnyin si ti ri lọwọ mi, ẹ mã ṣe wọn: Ọlọrun alafia yio si wà pẹlu nyin.

Paulu Dúpẹ́ fún Ẹ̀bùn

10 Ṣugbọn emi yọ̀ gidigidi ninu Oluwa pe, asiwá-asibọ̀ ero nyin tun sọji fun mi, eyiti ẹ ti nro nitotọ, ṣugbọn ẹnyin kò ni akokò ti o wọ̀.

11 Kì iṣe pe emi nsọ nitori aini: nitoripe ipòkipo ti mo ba wà, mo ti kọ́ lati ni itẹlọrùn ninu rẹ̀.

12 Mo mọ̀ bi ã ti iṣe di rirẹ̀-silẹ, mo mọ bi ã ti iṣe di pupọ: li ohunkohun ati li ohun gbogbo mo ti kọ́ aṣiri ati mã jẹ ajẹyó ati lati wà li aijẹ, lati mã ni anijù ati lati ṣe alaini.

13 Emi le ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹniti nfi agbara fun mi.

14 Ṣugbọn ẹnyin ṣeun gidigidi niti pe ẹnyin ṣe alabapin ninu ipọnju mi.

15 Ẹnyin papa si mọ̀ pẹlu, ẹnyin ara Filippi, pe li ibẹrẹ ihinrere, nigbati mo kuro ni Makedonia, kò si ijọ kan ti o ba mi ṣe alabapin niti gbigbà ati fifunni, bikoṣe ẹnyin nikanṣoṣo.

16 Nitori ni Tessalonika gidi, ẹnyin ranṣẹ, ẹ si tun ranṣẹ fun aini mi.

17 Kì iṣe nitoriti emi nfẹ ẹ̀bun na: ṣugbọn emi nfẹ eso ti yio mã di pupọ nitori nyin.

18 Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun.

19 Ṣugbọn Ọlọrun mi yio pèse ni kikún fun gbogbo aini nyin, gẹgẹ bi ọrọ̀ rẹ̀ ninu ogo ninu Kristi Jesu.

20 Ṣugbọn ogo ni fun Ọlọrun ati Baba wa lai ati lailai. Amin.

Ìdágbére

21 Ẹ kí olukuluku enia mimọ́ ninu Kristi Jesu. Awọn ara ti o wà pẹlu mi kí nyin.

22 Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin, papa awọn ti iṣe ti agbo ile Kesari.

23 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmi nyin. Amin.A kọ ọ si awọn ara Filippi lati Romu lọ lati ọwọ́ Epafroditu.

orí

1 2 3 4