3 Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi fun gbogbo iranti nyin ti mo nṣe,
4 Nigbagbogbo ninu gbogbo adura mi fun nyin li emi nfi ayọ̀ bẹ̀bẹ,
5 Nitori ìdapọ nyin ninu ihinrere lati ọjọ kini wá titi fi di isisiyi.
6 Ohun kan yi sa da mi loju, pe ẹniti o ti bẹ̀rẹ iṣẹ rere ninu nyin, yio ṣe aṣepe rẹ̀ titi fi di ọjọ Jesu Kristi:
7 Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere.
8 Nitori Ọlọrun li ẹlẹri mi, bi mo ti nṣafẹri nyin to gidigidi ninu iyọ́nu Jesu Kristi.
9 Eyi si ni mo ngbadura fun pe, ki ifẹ nyin ki o le mã pọ si i siwaju ati siwaju ninu imọ̀ ati imoye gbogbo.