7 Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.
8 Ẹ̀wẹ, ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, eyiti iṣe otitọ ninu rẹ̀ ati ninu nyin, nitori òkunkun nkọja lọ, imọlẹ otitọ si ti ntàn.
9 Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi.
10 Ẹniti o ba fẹran arakunrin rẹ̀, o ngbe inu imọlẹ, kò si si ohun ikọsẹ̀ ninu rẹ̀.
11 Ṣugbọn ẹniti o ba korira arakunrin rẹ̀ o ngbe inu òkunkun, o si nrìn ninu òkunkun, kò si mọ̀ ibiti on nrè, nitoriti òkunkun ti fọ ọ li oju.
12 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀.
13 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitori ẹnyin ti mọ̀ Baba.