1. Joh 5 YCE

Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé

1 OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu.

2 Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa fẹran awọn ọmọ Ọlọrun, nigbati awa fẹran Ọlọrun, ti a si npa ofin rẹ̀ mọ́.

3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.

4 Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa.

5 Tani ẹniti o ṣẹgun aiye, bikoṣe ẹniti o gbagbọ́ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu iṣe?

Ẹ̀rí nípa Ọmọ

6 Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí.

7 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ̀, ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹtẹ̃ta yi si jẹ ọ̀kan

8 Nitoripe awọn mẹta li o njẹri, Ẹmí, ati omi, ati ẹ̀jẹ: awọn mẹtẹ̃ta sì fi ohun ṣọkan.

9 Bi awa ba ngbà ẹ̀rí enia, ẹ̀rí Ọlọrun tobi ju: nitọri ẹri Ọlọrun li eyi pe O ti jẹri niti Ọmọ rẹ̀.

10 Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀.

11 Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀.

12 Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye.

Ìyè Ainipẹkun

13 Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́.

14 Eyi si ni igboiya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bère ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa:

15 Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà.

16 Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi.

17 Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú.

18 Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a.

19 Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì.

20 Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.

21 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu oriṣa. Amin.

orí

1 2 3 4 5