2. Joh 1 YCE

Ìkíni

1 EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu;

2 Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.

3 Õre-ọfẹ, ãnu, ati alafia, yio wà pẹlu wa, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, ninu otitọ ati ninu ifẹ.

Ẹ Máa Gbé Inú Ẹ̀kọ́ Kristi

4 Mo yọ̀ gidigidi pe mo ti ri ninu awọn ọmọ rẹ ti nrin ninu otitọ, ani bi awa ti gbà ofin lati ọdọ Baba.

5 Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.

6 Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.

7 Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.

8 Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.

9 Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.

10 Bi ẹnikẹni bá tọ̀ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ́ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i.

11 Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwọ́ ninu iṣẹ buburu rẹ̀.

Ìdágbére

12 Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.

13 Awọn ọmọ arabinrin rẹ ayanfẹ ki ọ. Amin.

orí

1