8 Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.
9 Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i.
10 Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.
11 Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.
12 Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo.
13 Ki ẹnu ki o máṣe yà nyin, ẹnyin ará mi, bi aiye ba korira nyin.
14 Awa mọ̀ pe awa ti rekọja lati inu ikú sinu ìye, nitoriti awa fẹràn awọn ará. Ẹniti kò ba ni ifẹ o ngbé inu ikú.