13 Tani yio si ṣe nyin ni ibi, bi ẹnyin ba jẹ onítara si ohun rere?
14 Ṣugbọn bi ẹnyin ba jìya nitori ododo, alafia ni: ẹ máṣe bẹru wọn, ki ẹ má si ṣe kọminu;
15 Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru.
16 Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi.
17 Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ.
18 Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:
19 Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: