1 NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ;
2 Ki ẹnyin ki o máṣe fi ìgba aiye nyin iyokù wà ninu ara mọ́ si ifẹkufẹ enia, bikoṣe si ifẹ Ọlọrun.
3 Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira.
4 Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu,
5 Awọn ẹniti yio jihin fun ẹniti o mura ati ṣe idajọ ãye on okú.
6 Nitori eyi li a sá ṣe wasu ihinrere fun awọn okú, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi enia nipa ti ara, ṣugbọn ki nwọn ki o le wà lãye si Ọlọrun nipa ti ẹmí.