16 Ṣugbọn bi o ba jìya bi Kristiani, ki oju ki o máṣe tì i; ṣugbọn ki o kuku yìn Ọlọrun logo ni orukọ yi.
17 Nitoriti ìgba na de, ti idajọ yio bẹ̀rẹ lati ile Ọlọrun wá: bi o ba si tète ti ọdọ wa bẹ̀rẹ, opin awọn ti kò gbà ihinrere Ọlọrun gbọ́ yio ha ti ri?
18 Biobaṣepe agbara káka li a fi gba olododo là, nibo ni alaiwà-bi-Ọlọrun on ẹlẹṣẹ yio gbé yọju si?
19 Nitorina ẹ jẹ ki awọn ti njìya gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun, fi ọkàn wọn le e lọwọ pẹlu ni rere iṣe, bi ẹnipe fun Ẹlẹda olõtọ.