2. Tes 2 YCE

Ẹni Ibi Nnì

1 ṢUGBỌN awa mbẹ̀ nyin, ará, nitori ti wíwa Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ̀,

2 Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.

3 Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé;

4 Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on.

5 Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wà lọdọ nyin, mo nsọ̀ nkan wọnyi fun nyin?

6 Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akokò rẹ̀.

7 Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro.

8 Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan:

9 Ani on, ẹniti wíwa rẹ̀ yio ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke,

10 Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.

11 Ati nitori eyi, Ọlọrun rán ohun ti nṣiṣẹ iṣina si wọn, ki nwọn ki o le gbà eke gbọ́:

12 Ki a le ṣe idajọ gbogbo awọn ti kò gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ni inu didùn ninu aiṣododo.

Ẹ̀yin tí Ọlọrun Yàn láti Gbà Là

13 Ṣugbọn iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, olufẹ nipa ti Oluwa, nitori lati àtetekọṣe li Ọlọrun ti yàn nyin si igbala ninu isọdimimọ́ Ẹmí ati igbagbọ́ otitọ:

14 Eyiti o ti pè nyin si nipa ihinrere wa, ki ẹnyin ki o le gbà ogo Jesu Kristi Oluwa wa.

15 Nitorina, ará, ẹ duro ṣinṣin, ki ẹ si dì ẹkọ́ wọnni mu ti a ti fi kọ́ nyin, yala nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe wa.

16 Njẹ ki Jesu Kristi Oluwa wa tikararẹ̀, ati Ọlọrun Baba wa, ẹniti o ti fẹ wa, ti o si ti fi itunu ainipẹkun ati ireti rere nipa ore-ọfẹ fun wa,

17 Ki o tù ọkan nyin ninu, ki o si fi ẹsẹ nyin mulẹ ninu iṣẹ ati ọrọ rere gbogbo.

orí

1 2 3