3 Ṣugbọn olododo li Oluwa, ẹniti yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, ti yio si pa nyin mọ́ kuro ninu ibi.
4 Awa si ni igbẹkẹle ninu Oluwa niti nyin, pe nkan wọnni ti a palaṣẹ fun nyin li ẹnyin nṣe ti ẹ o si mã ṣe.
5 Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.
6 Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa.
7 Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin;
8 Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn:
9 Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa.