5 Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu.
6 Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ.
7 Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro.
8 Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun;
9 Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye,
10 Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere,
11 Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ.