2. Tim 2 YCE

Ọmọ-Ogun Rere Ti Kristi Jesu

1 NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

2 Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu.

3 Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.

4 Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn.

5 Bi ẹnikẹni ba si njà, a kì dé e li ade, bikoṣepe o ba jà li aiṣe erú.

6 Àgbẹ ti o nṣe lãlã li o ni lati kọ́ mu ninu eso wọnni.

7 Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo.

8 Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi,

9 Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun.

10 Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun.

11 Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè:

12 Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa.

13 Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.

14 Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ.

15 Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ.

16 Ṣugbọn yà kuro ninu ọ̀rọ asan, nitoriti nwọn ó mã lọ siwaju ninu aiwa-bi-Ọlọrun,

17 Ọrọ wọn yio si mã jẹ bi egbò kikẹ̀; ninu awọn ẹniti Himeneu ati Filetu wà;

18 Awọn ẹniti o ti ṣìna niti otitọ, ti nwipe ajinde ti kọja na; ti nwọn si mbì igbagbọ́ awọn miran ṣubu.

19 Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.

20 Ṣugbọn ninu ile nla, kì iṣe kìki ohun elo wura ati ti fadaka nikan ni mbẹ nibẹ̀, ṣugbọn ti igi ati ti amọ̀ pẹlu; ati omiran si ọlá, ati omiran si ailọlá.

21 Bi ẹnikẹni ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ kuro ninu wọnyi, on ó jẹ ohun èlo si ọlá, ti a yà si ọ̀tọ, ti o si yẹ fun ìlo bãle, ti a si ti pèse silẹ si iṣẹ rere gbogbo.

22 Mã sá fun ifẹkufẹ ewe: si mã lepa ododo, igbagbọ́, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá.

23 Ṣugbọn ibẽre wère ati alaini ẹkọ́ ninu ni ki o kọ̀, bi o ti mọ̀ pe nwọn ama dá ìja silẹ.

24 Iranṣẹ Oluwa kò si gbọdọ jà; bikoṣe ki o jẹ ẹni pẹlẹ si enia gbogbo, ẹniti o le kọ́ni, onisũru,

25 Ẹniti yio mã kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; boya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ;

26 Nwọn o si le sọji kuro ninu idẹkun Èṣu, awọn ti a ti dì ni igbekun lati ọwọ́ rẹ̀ wá si ifẹ rẹ̀.

orí

1 2 3 4