1 JAKỌBU, iranṣẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa, si awọn ẹ̀ya mejila ti o túka kiri, alafia.
2 Ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba bọ́ sinu onirũru idanwò, ẹ kà gbogbo rẹ̀ si ayọ;
3 Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru.
4 Ṣugbọn ẹ jẹ ki sũru ki o ṣe iṣẹ aṣepé, ki ẹnyin ki o le jẹ pipe ati ailabuku, ki o má kù ohun kan fun ẹnikẹni.