Jak 5 YCE

Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀

1 Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin.

2 Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin.

3 Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin.

4 Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun.

5 Ẹnyin ti jẹ adùn li aiye, ẹnyin si ti fi ara nyin fun aiye jijẹ; ẹnyin ti bọ́ li ọjọ pipa.

6 Ẹnyin ti da ẹbi fun olododo, ẹ si ti pa a; on kò kọ oju ija si nyin.

Sùúrù ati Adura

7 Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo.

8 Ẹnyin pẹlu ẹ mu sũru; ẹ fi ọkàn nyin balẹ̀: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ.

9 Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun.

10 Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru.

11 Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu.

12 Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.

13 Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́.

14 Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa:

15 Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.

16 Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.

17 Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa.

18 O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.

19 Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;

20 Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

orí

1 2 3 4 5