12 Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yege, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ.
13 Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò:
14 Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ.
15 Njẹ, ifẹkufẹ na nigbati o ba lóyun, a bí ẹ̀ṣẹ: ati ẹ̀ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bí ikú.
16 Ki a má ṣe tan nyin jẹ, ẹnyin ará mi olufẹ.
17 Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.
18 Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀.