3 Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru.
4 Ṣugbọn ẹ jẹ ki sũru ki o ṣe iṣẹ aṣepé, ki ẹnyin ki o le jẹ pipe ati ailabuku, ki o má kù ohun kan fun ẹnikẹni.
5 Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia ni ọ̀pọlọpọ, ti kì isi ibaniwi; a o si fifun u.
6 Ṣugbọn ki o bère ni igbagbọ́, li aiṣiyemeji rara. Nitori ẹniti o nṣiyemeji dabi ìgbi omi okun, ti nti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin ti a si nrú soke.
7 Nitori ki iru enia bẹ̃ máṣe rò pe, on yio ri ohunkohun gbà lọwọ Oluwa;
8 Enia oniyemeji jẹ alaiduro ni ọ̀na rẹ̀ gbogbo.
9 Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀.