8 Enia oniyemeji jẹ alaiduro ni ọ̀na rẹ̀ gbogbo.
9 Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀.
10 Ati ọlọrọ̀, ni irẹ̀silẹ rẹ̀, nitori bi itanná koriko ni yio kọja lọ.
11 Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.
12 Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yege, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ.
13 Ki ẹnikẹni ti a danwò máṣe wipe, Lati ọwọ́ Ọlọrun li a ti dán mi wò: nitori a kò le fi buburu dán Ọlọrun wò, on na kì isi idán ẹnikẹni wò:
14 Ṣugbọn olukuluku ni a ndanwò, nigbati a ba ti ọwọ́ ifẹkufẹ ara rẹ̀ fà a lọ ti a si tàn a jẹ.