1 NIBO ni ogun ti wá, nibo ni ija si ti wá larin nyin? lati inu eyi ha kọ? lati inu ifẹkufẹ ara nyin, ti njagun ninu awọn ẹ̀ya-ara nyin?
2 Ẹnyin nfẹ, ẹ kò si ni: ẹnyin npa, ẹ si nṣe ilara, ẹ kò si le ni: ẹnyin njà, ẹnyin si njagun; ẹ ko ni, nitoriti ẹnyin kò bère.
3 Ẹnyin bère, ẹ kò si ri gbà, nitoriti ẹnyin ṣì i bère, ki ẹnyin ki o le lò o fun ifẹkufẹ ara nyin.
4 Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.
5 Ẹnyin ṣebi iwe-mimọ́ sọ lasan pe, Ẹmí ti o fi sinu wa njowu gidigidi lori wa?