13 Omi okun ti nrú, ti nhó ifõfó itiju ara wọn jade; alarinkiri irawọ, awọn ti a pa òkunkun biribiri mọ́ dè lailai.
14 Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́,
15 Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.
16 Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.
17 Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi;
18 Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn.
19 Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí.