17 Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi;
18 Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn.
19 Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí.
20 Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́,
21 Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun.
22 Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han:
23 Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri.