3 Inu ẹniti a ti fi gbogbo iṣura ọgbọ́n ati ti ìmọ pamọ́ si.
4 Eyi ni mo si nwi, ki ẹnikẹni ki o má bã fi ọ̀rọ ẹtàn mu nyin ṣina.
5 Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi.
6 Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹ̃ni ki ẹ mã rìn ninu rẹ̀:
7 Ki ẹ fi gbongbo mulẹ, ki a si gbe nyin ro ninu rẹ̀, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ nyin, gẹgẹ bi a ti kọ́ nyin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ.
8 Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi.
9 Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara.