Kol 3 YCE

1 NJẸ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mã ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ́ ọtun Ọlọrun.

2 Ẹ mã ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye.

3 Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.

4 Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo.

5 Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa:

6 Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran.

7 Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi.

8 Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin.

9 Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀;

10 Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a:

11 Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo.

12 Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra;

13 Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu.

14 Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé.

15 Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ.

16 Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.

17 Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.

Ìbálò Onigbagbọ pẹlu Ara Wọn

18 Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Oluwa.

19 Ẹnyin ọkọ, ẹ mã fẹran awọn aya nyin, ẹ má si ṣe korò si wọn.

20 Ẹnyin ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin li ohun gbogbo: nitori eyi dara gidigidi ninu Oluwa.

21 Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu, ki nwọn má bã rẹwẹsi.

22 Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara li ohun gbogbo; kì iṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewù enia; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹ̀ru Ọlọrun:

23 Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia;

24 Ki ẹ mọ̀ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbà ère ogun: nitori ẹnyin nsìn Oluwa Kristi.

25 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yio gbà pada nitori aiṣododo na ti o ti ṣe: kò si si ojuṣãju enia.

orí

1 2 3 4