1 ẸNYIN oluwa, ẹ ma fi eyiti o tọ́ ti o si dọgba fun awọn ọmọ-ọdọ nyin; ki ẹ si mọ̀ pe ẹnyin pẹlu ni Oluwa kan li ọrun.
2 Ẹ mã duro ṣinṣin ninu adura igbà, ki ẹ si mã ṣọra ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ;
3 Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu:
4 Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.
5 Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba.
6 Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn.
7 Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: