1 Ngbà náà ni Jónà gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,
2 Ó sì wí pé:“Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa,òun sì gbọ́ ohùn mi.Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún iraǹwọ́,ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.
3 Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú,ní àárin òkun,ìṣàn omi sì yí mi káàkiri;gbogbo bíbì omi àti rírú omiré kọjá lórí mi.
4 Nígbà náà ni mo wí pé,‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ;ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ èmi yóò túnmáa wo ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.’
5 Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;ibú yí mi káàkiri,a fi koríko odò wé mi lórí.
6 Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá;ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí:ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi.
7 “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi,èmi rántí rẹ, Olúwa,àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.
8 “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èkékọ àánú ara wọn sílẹ̀.
9 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rúbọ sí ọ.Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.‘Igbàlà wá láti ọdọ Olúwa.’ ”
10 Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.