1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jónà wá nigbà kejì wí pé:
2 “Dìde lọ sí Nínéfè, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”
3 Jónà sì dìde ó lọ sí Nínéfè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Nínéfè jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.
4 Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Nínéfè wó.”
5 Àwọn ènìyàn Nínéfè sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ lati orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.
6 Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.
7 Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Nínéfè pé:“Kí a la Nínéfè já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbààgbà rẹ̀ pé:“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́-ẹran tàbí agbo-ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi.