8 Ó sì ṣe, nígbà tí òòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jónà lórí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”
9 Ọlọ́run sì wí fún Jónà pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, Ó tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
10 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
11 Ṣùgbọ́n Nínéfè ní jù ọ̀kẹ́-mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ilú ńlá náà?”