Málákì 3:10-16 BMY

10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ báà lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́ sílẹ̀ jáde fún yín, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì àyè láti gbà á.

11 Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

12 “Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí ti yín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wuni,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

13 “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.“Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’

14 “Ẹ̀yín ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń sọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ ogun?

15 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún Ní otitọ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Olúwa wò ni a dá sí.’ ”

16 Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, ti wọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.