5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín búkí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókèkí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú
6 Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wábí ìkuku èéfíntí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lárapẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò?
7 Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Sólómónì,Àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,Àwọn akọni Ísírẹ́lì,
8 Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru
9 Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;Ó fi igi Lébánónì ṣe é.
10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”
11 Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì,kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé,Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé eNí ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.