Orin Sólómónì 5 BMY

1 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́

2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn.“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, aláìlábàwọ́n miOrí mi kún fún omi ìrì,irun mi kún fún òtútù òru.”

3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà miṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?Mo ti wẹ ẹsẹ̀ miṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùninú mi sì yọ́ sí i

5 Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣànsí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn

6 Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn

7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mibí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́;wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yínbí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi.

9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọÌwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọtí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀?

10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́nó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.

11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò

12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbàní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn,tí a fi wàrà wẹ̀,tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́

13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràríti ó sun òórùn tùràrí dídùnÈtè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílìó ń kán òjíá olóòórùn dídùn

14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíkáAra rẹ̀ rí bí i eyín erin dídántí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

15 Ẹṣẹ̀ rẹ̀ rí bi i òpó mábùtí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradáraÌrísí rẹ̀ rí bí igi kédárì Lẹ́bánónì,tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.

16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ó wu ni pátapáta.Áà! Ẹ̀yín ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Èyí ní olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8