Orin Sólómónì 1 BMY

1 Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì

2 Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.

3 Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jádeAbájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ.

4 Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíáỌba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!

5 Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Dúdú bí àgọ́ KédárìBí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì

6 Má ṣe wò mí nítorí wí pé mo dúdúNítorí òòrùn mú mi dúdúỌmọkùnrin ìyá mi bínú símiÓ sì fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà.Ọgbà àjàrà tèmi ni èmi kò tọ́jú

7 Ṣọ fún mi ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́,Níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ.Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán.Kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin aṣánNí ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

8 Bí ìwọ kò bá mọ̀,Ìwọ arẹwà jùlọ nínú àwọn obìnrin.Bá ọ̀nà ti agbo ẹran rìn lọ.Kí o sì bọ́ àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ.Ní ẹ̀bá àgọ́ àwọn olùsọ́ àgùntàn.

9 Olùfẹ́ mi,Mo fi ọ́ wé ẹṣin mi nínú kẹ̀kẹ́ Fáráò.

10 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dára ní ohun ọ̀ṣọ́,Ọrùn rẹ sì yẹ ọ̀ṣọ́ ìlẹ̀kẹ̀

11 A ó fi wúrà ṣe òrùka etí fún ọ,A ó fi fàdákà ṣe ìlẹ̀kẹ̀.

12 Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀.Òróró ìkunra mi tú òórùn jáde.

13 Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi.Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi.

14 Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí miLáti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì.

15 Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.

16 Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni!Ibùsùn wa ní ìtura.

17 Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárìẸkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8