3 Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimélékì, ọkọ Náómì kú, ó sì ku òun (Náómì) pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì.
4 Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Móábù méjì, orúkọ, ọ̀kan ń jẹ́ Órípà, èkejì sì ń jẹ́ Rúùtù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá,
5 Málónì àti Kílíónì náà sì kú, Náómì sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún-un mọ́.
6 Nígbà tí Náómì gbọ́ ní Móábù tí ó wà wí pé Olúwa ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fí fún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀.
7 Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò wọn padà sí ilẹ̀ Júdà.
8 Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.
9 Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.”Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan.