Rúùtù 1:8-14 BMY

8 Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Náómì wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnikọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Olúwa ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú.

9 Kí Olúwa kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.”Náómì sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sunkún kíkan kíkan.

10 Wọ́n sì wí fún-un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”

11 Ṣùgbọ́n Náómì dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le se ọkọ yin?

12 Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, mo ti dàgbà jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí mo ti lẹ̀ ní èrò wí pé ìrètí sì wà fún mi, tí mo sì fẹ́ ọkọ mìíràn lónìí tí mo sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn,

13 ṣé ẹ̀yin le è dúró dìgbà tí wọ́n bá dàgbà láì fẹ́ ọkọ mìíràn nítorí wọn ni? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi. Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún mi ju bí ó ti jẹ́ fún ẹ̀yin lọ nítorí pé ọwọ́ Olúwa ti fìyà jẹ mi lọ́nà tó pamí lára gidi.”

14 Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún sunkún kíkorò. Nígbà náà ní Órípà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rúùtù dì mọ́ ọn síbẹ̀.