14 Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́ ó ń gbé inú ikú.
15 Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí o ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.
16 Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.
17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?
18 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.
19 Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì dá ara wa lójú níwájú rẹ̀.
20 Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.