9 Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀.
10 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.
11 Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀.
12 Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
13 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́.
14 Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa;
15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.