1 Pétérù, Àpósítélì Jésù Kírísítì,Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, ti wọn tú káàkiri sí Pọ́ńtù, Gálátíà, Kápádókíà, Ésíà, àti Bítíníà,
2 àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì:Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.
3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlárẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jésù Kírísítì kúrò nínú òkú,
4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í sá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,
5 Ẹ̀yin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyin.