1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn.
2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín:
3 Kí ọ̀sọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀sọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;
4 Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó farasìn ní ọkàn, nínú ọ̀sọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.
5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbaànì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi sẹ ara wọn lọ́sọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ tiwọn.
6 Gẹ́gẹ́ bí Sárà ti gbọ́ ti Ábúráhámù, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.
7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi Òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.
8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀
9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogun ìbùkún.
10 Nítorí,“Ẹni tí yóò bá fẹ ìyè,ti yóò sì rí ọjọ́ rere,kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:ṣùgbọ́n ojú Olúwa dojúkọ àwọn tí ń ṣe búburú.”
13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere?
14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, àlàáfíà ni: ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú;
15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kírísítì bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń bèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.
16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí-ọkàn rere bi wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kírísítì.
17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣiṣé búburú lọ.
18 Nítorí tí Kírísítì pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí:
19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú:
20 Àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sáà kan ní ọjọ́ Nóà, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba àwọn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ.
21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsìnyìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jésù Kírísítì.
22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹ́riba lábẹ́ rẹ̀.