1 Pétérù 4 BMY

Ìgbé Ayé Fún Ọlọ́run

1 Ǹjẹ́ bí Kírísítì ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;

2 Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.

3 Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rìnrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.

4 Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejú ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.

5 Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.

6 Nítorí èyí ní a ṣá ṣe wàásù ìyìn rere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

7 Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa sọra nínú àdúrà.

8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrin ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

9 Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.

10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrin ara yín, bí ìríjú rere tí oníruúrú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí í ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fifún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. (Àmín).

Jíjìyà Pé Ó Jẹ Onígbàgbọ́

12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrin yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín:

13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábàápín ìyà Kírísítì, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn.

14 Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín (ní ọ̀dọ̀ tí wọn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi, ṣùgbọ́n ní ọ̀dọ̀ ti yín a yìn ín lógo.)

15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí àpànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣé búburú, tàbí bí ẹni tí ń tọjúbọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.

16 Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí kírísítẹ́nì kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.

17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀hìn àwọn tí kò gba ìyìn rere Ọlọ́run yó ha ti rí?

18 “Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́sẹ̀ yóò gbe yọjú sí?”

19 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtọ́ lọ́wọ́.

orí

1 2 3 4 5