1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn.
2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín:
3 Kí ọ̀sọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀sọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;
4 Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó farasìn ní ọkàn, nínú ọ̀sọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.
5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbaànì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi sẹ ara wọn lọ́sọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ tiwọn.
6 Gẹ́gẹ́ bí Sárà ti gbọ́ ti Ábúráhámù, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.
7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi Òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.