6 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mi Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.
7 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹrẹ fún gbogbo àwọn Kírísírẹ́nì tó wà ní agbégbé Makedóníà àti Ákáyà.
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbégbé Makedóníà àti Ákáyà lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀.
9 Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn.
10 àti láti fi ojú sọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jésù, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.